Sale!

PRAYER KINGDOM

300.00 200.00

 

 

Edomu ni Boko Haramu, bi o tilẹ ga kan ọrun yi o di ilẹ ni orukọ Jesu, Israẹli ni Buhari, ore-ọfẹ Buhari pọ ju gbogbo aarẹ Nigeria lọ titi de opin ayeraye…

Buhari ni ilẹ̀ kan, o pin si ọna mẹrin, o fi t´ẹyẹ fun ẹyẹ, ki àjẹ́ má yọ lẹnu mọ, o fi ti ẹgun fun ẹgun, ki èpè máse ja Buhari, o ti fi ti àpáta fun àpáta ki o ba le rọ ọ lọrùn, o wa fi ti Oluwa fun Oluwa, o jogun Nigeria to nṣàn fun warà ati fun oyin, kò ni bàjẹ́ ni orukọ Jesu….

Ọdọ-Agutan ni imọlẹ Buhari, kì í ṣe NEPA, òkunkun ayé kò lè bori rẹ ni orukọ Jesu…

Buhari ti fi okuta Bẹtẹli ṣe irọri, o ti ta ororo le lori, o ti di ilé Oluwa, o ti ri ẹnubode ọrun, ẹnu-ọna isa òkú kò lè bori rẹ ni orukọ Jesu…

Iwẹfà to pa ọjọ isimi mọ ti ko fi Jimọh oloyin ṣe ere, oun ni Muhammadu Buhari, kò gbudọ ṣe aṣeti, o ti ṣe alabapade angẹli Mikaẹli, Gabriẹli, gbogbo wọn ni wọn parapọ ti wọn ti súre fun, arayé kò gbudọ binu si, ara ọrun ti yọnu si…

Akarà Jesu ni ara Buhari, ago Oluwa ni ẹjẹ̀ rẹ, ẹniti o ba jẹ akarà, ti o mu ago Oluwa laiyẹ yoo jẹbi ni orukọ Jesu…

Buhari ti ba ara ọrun rin, o ti jẹ ounjẹ angẹli, Àsápa, erò ẹyin ọta, kò patan, kò kú tan Samaria ni Buhari ilu ààbò, oju ọgbẹ gbẹ, kò ni kú bikose yiye ni orukọ Jesu…

Ori Buhari ni wọn fi pe, atari ẹniti a ya si ọtọ̀ laarin President, ọna obinrin lo rin wọ inu ayé, alafia ni fun Muhammadu Buhari, kolobo ororo rẹ ko ni gbẹ, tọsan toru iná Mose kò gbudọ kú ninu agọ, atupa rẹ kò gbudọ kú titi di ọjọ alẹ, anadalẹ la n na ọja, bi ọjọ ba yọ o di alẹ ki o to wọ, bi o ba ri bẹẹ Oluwa yóò mu ọjọ rẹ duro, ikoko iyẹfun rẹ kò ni gbẹ, niwọn igba ti Jesu ba nbẹ ni aaye, ni orukọ Jesu Kristi Oluwa wa

 

Categories: ,

Reviews

There are no reviews yet.

Be the first to review “PRAYER KINGDOM”

Your email address will not be published. Required fields are marked *