ÀDÚRÀ ÌDÁNDÈ LỌWỌ AYÉ

200.00

Bi afẹ́fẹ́ ba nfẹ́, kò si ẹniti o mọ ibiti o gbe ti wa, bi mo ba sùn, irinajo ni mo lọ, Àmọ̀na lo fi ọ̀nà hàn mi ti mo fi padà wá si ori ibùsùn, n ó mọ ọna ire ni ọdun yi….

Èso mẹta ninu ọgbà, ọkan ti baba, ọkan ti ọmọ, ọkan ti iya, ti baba ni mo fi jẹ ọba lori ohun gbogbo, ti ọmọ ni mo fi fọ ejò láéláé ni ori, ti iya ni o sọ ènìyàn di oni ìhòhò, ọ̀pọ̀tọ́ ti wọn fi ṣe ìbàntẹ́, ni Jesu fi bu ni ọjọ isinmi ọ̀pẹ, ó gbẹ tewé-tewé, o gbẹ tegbò-tegbò, iya kú, bàbá kò kú, Jesu ti wọ̀ mi ni aṣọ iyawo, ki nba ẹgbẹ́ pe…

Òkun Pupa kò ni gbe ọmọ Israẹli lọ, iná kò ni jo igbẹ́ Mose, Òkè Sioni kò ṣe ṣi ni idi, ibiti alaisàn wa ni Jesu ti lọ ṣe ìwòsàn rẹ̀, ki ire ati ayọ wa ba mi gbe…

Nigbati mo ba le awọn ọta mi ba, Erin ni mi, ki n máa fi ọla mi, itakun kan kò gbudọ̀ de mi ni ọnà, Ejò Idẹ́ ni mi, ikọ́ ayé kan kò gbudọ fa mi pada sẹhin, emi ni Ẹyẹ Idi, ki nmáa fo ni oke loke, n ó gbudọ fi ori sọ igi…

NOTE: You will need to download an E-book reader on your mobile device before you can access the book.

Additional information

NOTE

NOTE: You will need to download an E-book reader on your mobile device before you can access the book.

Reviews

There are no reviews yet.

Be the first to review “ÀDÚRÀ ÌDÁNDÈ LỌWỌ AYÉ”

Your email address will not be published. Required fields are marked *